Oríkì Ìlú Arà.

by Adabanija Kamorudeen

Ìsójà lówó omo Ekòló nyoò, Ààyè ö j’ajá mo m’ãgbò sorò,
Mo pa’kún nla mo mún t’oro,
Mo p’òdù Òyà, mofi d’olojo ‘bè.

Ààyè ò ma gbin kìn lé mi Lórí,
E má ba jà, baba re ló fi kárin kése Jo.

M’ba ni nb’òbinrin ò l’ómún,
Èmi mà mà l’ómún, ààyè òun mo mún jò’yá mi.

Ààyè òún, ilé Ìgbín gbà’ gbín,
Ilé ahun t’áhun yan.

Babami, Òdèdè ahun kò gb’àlejò mejì.Omo eni tí ògbón, omo eni tí ò m’òràn,

Ni bá won wípé olórí nlalá nbe l’ode Òjo,
Al’átàrí kèlèbò nbe l’ójà Arà.

ìgbà t’emi gbón, t’emi si m’òràn,
Mo l’ómo Olówó ní nbe l’óde Òjo, omo Olórò ni nbe l’oja Ara,

Related Posts

Leave a Comment

1 + 6 =